4 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 5 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, ẹnu yà á gan-an.