37 “Bákan náà, ẹ yéé dáni lẹ́jọ́, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́jọ́;+ ẹ yéé dáni lẹ́bi, ó sì dájú pé a ò ní dá yín lẹ́bi. Ẹ máa dárí jini,* a sì máa dárí jì yín.*+
2Nítorí náà, ìwọ èèyàn, o ò ní àwíjàre, ẹni tó wù kí o jẹ́,+ tí o bá ṣèdájọ́; torí nígbà tí o bá ṣèdájọ́ ẹlòmíì, ara rẹ lò ń dá lẹ́bi, nítorí ìwọ tí ò ń ṣèdájọ́ ń ṣe ohun kan náà.+