ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Máàkù 1:29-34
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 Wọ́n wá kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n sì lọ sí ilé Símónì àti Áńdérù pẹ̀lú Jémíìsì àti Jòhánù.+ 30 Àìsàn ibà dá ìyá ìyàwó Símónì+ dùbúlẹ̀, wọ́n sì sọ fún un nípa rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 31 Ó lọ bá obìnrin náà, ó dì í lọ́wọ́ mú, ó sì gbé e dìde. Ibà náà sì lọ, obìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

      32 Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, tí oòrùn ti wọ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú gbogbo àwọn tó ní àìlera àti àwọn tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu wá sọ́dọ̀ rẹ̀;+ 33 gbogbo ìlú sì kóra jọ sí ẹnu ilẹ̀kùn. 34 Torí náà, ó wo ọ̀pọ̀ àwọn tí oríṣiríṣi àìsàn ń yọ lẹ́nu sàn,+ ó sì lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, àmọ́ kì í jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.*

  • Lúùkù 4:38-41
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 38 Lẹ́yìn tó kúrò nínú sínágọ́gù, ó wọ ilé Símónì. Akọ ibà ń ṣe ìyá ìyàwó Símónì, wọ́n sì ní kó ràn án lọ́wọ́.+ 39 Torí náà, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin náà, ó sì bá ibà náà wí, ibà náà sì lọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin náà dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

      40 Àmọ́ nígbà tí oòrùn ń wọ̀, gbogbo àwọn tí èèyàn wọn ń ṣàìsàn, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àrùn, mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó ń wò wọ́n sàn.+ 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù tún jáde lára ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n ń kígbe, wọ́n sì ń sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+ Àmọ́ ó bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀,+ torí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́