-
Máàkù 5:7-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ó sì ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Fi Ọlọ́run búra fún mi pé o ò ní dá mi lóró.”+ 8 Torí Jésù ti ń sọ fún un pé: “Jáde nínú ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́.”+ 9 Àmọ́ Jésù bi í pé: “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Líjíónì lorúkọ mi, torí a pọ̀.” 10 Ó ṣáà ń bẹ Jésù pé kó má ṣe lé àwọn ẹ̀mí náà jáde kúrò ní ilẹ̀ náà.+
-
-
Lúùkù 8:28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Bó ṣe rí Jésù, ó kígbe, ó sì wólẹ̀ síwájú rẹ̀, ó wá ké jáde pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Mo bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.”+
-