34 Torí èyí, mò ń rán àwọn wòlíì,+ àwọn amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba+ sí yín. Ẹ máa pa àwọn kan lára wọn,+ ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi,* ẹ máa na àwọn kan lára wọn+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn+ láti ìlú dé ìlú,
9 “Ní tiyín, ẹ máa ṣọ́ra yín. Àwọn èèyàn máa fà yín lé àwọn ilé ẹjọ́ àdúgbò lọ́wọ́,+ wọ́n máa lù yín nínú àwọn sínágọ́gù,+ ẹ sì máa dúró níwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún wọn.+
12 “Àmọ́ kí gbogbo àwọn nǹkan yìí tó ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín,+ wọ́n á fà yín lé àwọn sínágọ́gù lọ́wọ́, wọ́n á sì fi yín sẹ́wọ̀n. Wọ́n máa mú yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi.+13 Èyí máa jẹ́ kí ẹ lè jẹ́rìí.