40 “Ó ti fọ́ ojú wọn, ó sì ti mú kí ọkàn wọn le, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn ríran, kí ọkàn wọn má sì lóye, kí wọ́n lè yí pa dà, kí n sì mú wọn lára dá.”+
14 Àmọ́ èrò inú wọn ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́.+ Nítorí títí di òní yìí, a kò ká ìbòjú yẹn kúrò tí a bá ń ka májẹ̀mú láéláé,+ torí ipasẹ̀ Kristi nìkan la fi ń mú un kúrò.+