32 Àmọ́ Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ pé: “Àánú àwọn èèyàn yìí ń ṣe mí,+ torí ọjọ́ kẹta nìyí tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi, tí wọn ò sì ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ. Mi ò fẹ́ kí wọ́n lọ láìjẹun,* torí kí okun wọn má bàa tán lójú ọ̀nà.”+
17 Bákan náà, ó ní láti dà bí “àwọn arákùnrin” rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà,+ kó lè di àlùfáà àgbà tó jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ nínú àwọn ohun tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run, kó lè rú ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn.+