-
Mátíù 23:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè!+ torí pé ẹ̀ ń rìnrìn àjò gba orí òkun àti ilẹ̀ láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe,* tó bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ ọ́ di ẹni tí Gẹ̀hẹ́nà* tọ́ sí ní ìlọ́po méjì jù yín lọ.
16 “Ẹ gbé, ẹ̀yin afọ́jú tó ń fini mọ̀nà,+ tó ń sọ pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́ńpìlì búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹ́ńpìlì búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.’+
-
-
Lúùkù 6:39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Ó tún sọ àpèjúwe kan fún wọn pé: “Afọ́jú kò lè fi afọ́jú mọ̀nà, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Inú kòtò ni àwọn méjèèjì máa ṣubú sí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+
-