-
Máàkù 8:27-29Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá lọ sí àwọn abúlé Kesaríà Fílípì, ó sì ń bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú ọ̀nà pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 28 Wọ́n sọ fún un pé: “Jòhánù Arinibọmi,+ àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà,+ àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì.” 29 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” Pétérù dá a lóhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà.”+
-
-
Lúùkù 9:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Lẹ́yìn náà, bó ṣe ń dá gbàdúrà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bá a, ó sì bi wọ́n pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 19 Wọ́n fèsì pé: “Jòhánù Arinibọmi, àmọ́ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà, àwọn míì sì ń sọ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì àtijọ́ ti dìde.”+ 20 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ sọ pé mo jẹ́?” Pétérù dáhùn pé: “Kristi ti Ọlọ́run.”+
-