21 Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó rí àwọn méjì míì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀.+ Inú ọkọ̀ ojú omi ni wọ́n wà pẹ̀lú Sébédè bàbá wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe, ó sì pè wọ́n.+
55 Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wòran láti ọ̀ọ́kán, àwọn tó tẹ̀ lé Jésù wá láti Gálílì kí wọ́n lè ṣe ìránṣẹ́ fún un;+56 lára wọn ni Màríà Magidalénì, Màríà ìyá Jémíìsì àti Jósè àti ìyá àwọn ọmọ Sébédè.+