28 Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Ágábù + dìde, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí pé ìyàn ńlá máa tó mú ní gbogbo ilẹ̀ ayé+ tí à ń gbé, èyí sì ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ lásìkò Kíláúdíù.
6 Mo gbọ́ tí nǹkan kan dún bí ohùn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ó sọ pé: “Òṣùwọ̀n kúọ̀tì* àlìkámà* kan fún owó dínárì*+ kan àti òṣùwọ̀n kúọ̀tì mẹ́ta ọkà báálì fún owó dínárì kan; má sì pa òróró ólífì àti wáìnì lára.”+