-
Lúùkù 12:42-44Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
42 Olúwa sọ pé: “Ní tòótọ́, ta ni ìríjú olóòótọ́* náà, tó jẹ́ olóye,* tí ọ̀gá rẹ̀ máa yàn pé kó bójú tó àwọn ìránṣẹ́* rẹ̀, kó máa fún wọn ní ìwọ̀n oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?+ 43 Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀! 44 Mò ń sọ fún yín ní tòótọ́, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.
-