12 Torí náà, ó sọ pé: “Ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà+ kó lè lọ gba agbára láti jọba, kó sì pa dà. 13 Ó pe mẹ́wàá lára àwọn ẹrú rẹ̀, ó fún wọn ní mínà* mẹ́wàá, ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ máa fi ṣòwò títí màá fi dé.’+