-
Lúùkù 22:67-71Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
67 “Sọ fún wa, tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà.”+ Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ sọ fún yín, ẹ ò ní gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ rárá. 68 Bákan náà, tí mo bá bi yín ní ìbéèrè, ẹ ò ní dáhùn. 69 Àmọ́ láti ìsinsìnyí lọ, Ọmọ èèyàn+ máa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”+ 70 Ni gbogbo wọn bá sọ pé: “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọ́run?” Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ń sọ pé èmi ni.” 71 Wọ́n sọ pé: “Kí la tún nílò ẹ̀rí fún? Torí a ti fetí ara wa gbọ́ ọ lẹ́nu òun fúnra rẹ̀.”+
-