-
Mátíù 8:24-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Wò ó! ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí í jà lórí òkun, débi pé ìgbì òkun ń bo ọkọ̀ náà; àmọ́ ó ń sùn.+ 25 Ni wọ́n bá wá jí i, wọ́n sọ pé: “Olúwa, gbà wá, a ti fẹ́ ṣègbé!” 26 Ṣùgbọ́n ó sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín* tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?”+ Ó wá dìde, ó sì bá ìjì àti òkun wí, ni gbogbo ẹ̀ bá pa rọ́rọ́.+ 27 Ẹnu ya àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì sọ pé: “Irú èèyàn wo nìyí? Ìjì àti òkun pàápàá ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”
-
-
Lúùkù 8:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ lórí omi, ó sùn lọ. Ìjì líle kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í jà lórí adágún náà, omi wá ń rọ́ wọnú ọkọ̀ wọn, wọ́n sì wà nínú ewu.+ 24 Torí náà, wọ́n lọ jí i, wọ́n ní: “Olùkọ́, Olùkọ́, a ti fẹ́ ṣègbé!” Ló bá dìde, ó bá ìjì àti omi tó ń ru gùdù náà wí, wọ́n sì rọlẹ̀, wọ́n pa rọ́rọ́.+ 25 Ó wá sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò nígbàgbọ́ ni?” Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n ń sọ fúnra wọn pé: “Ta lẹni yìí gan-an? Torí ó ń pàṣẹ fún ìjì àti omi pàápàá, wọ́n sì ń gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu.”+
-