-
Mátíù 14:6-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí+ Hẹ́rọ́dù, ọmọbìnrin Hẹrodíà jó níbi ayẹyẹ náà, ó sì múnú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an+ 7 débi pé ó ṣèlérí, ó sì búra pé òun máa fún un ní ohunkóhun tó bá béèrè. 8 Ìyá ọmọbìnrin náà kọ́ ọ ní ohun tó máa sọ, ó sì sọ pé: “Fún mi ní orí Jòhánù Arinibọmi níbí yìí nínú àwo pẹrẹsẹ.”+ 9 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ọba ò dùn rárá, ó pàṣẹ pé kí wọ́n fún un, torí pé ó ti búra àti torí àwọn tó ń bá a jẹun.* 10 Ó wá ránṣẹ́ pé kí wọ́n lọ bẹ́ orí Jòhánù nínú ẹ̀wọ̀n. 11 Wọ́n gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ, wọ́n sì fún ọmọbìnrin náà, ó wá gbé e wá fún ìyá rẹ̀. 12 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá gbé òkú rẹ̀ kúrò, wọ́n sì sin ín; wọ́n wá ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Jésù.
-