-
Mátíù 14:34-36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Wọ́n sọdá, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+
35 Nígbà tí àwọn èèyàn ibẹ̀ wá mọ̀ pé òun ni, wọ́n ránṣẹ́ sí gbogbo ìgbèríko tó wà ní àyíká yẹn, àwọn èèyàn sì mú gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí àwọn ṣáà fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+ ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá pátápátá.
-