21 Nígbà tó kúrò níbẹ̀, ó rí àwọn méjì míì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, Jémíìsì ọmọ Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀.+ Inú ọkọ̀ ojú omi ni wọ́n wà pẹ̀lú Sébédè bàbá wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe, ó sì pè wọ́n.+ 22 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi náà àti bàbá wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e.