-
Jòhánù 2:14-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Ó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà+ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì rí àwọn tó ń pààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn. 15 Torí náà, ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì lé gbogbo àwọn tó ní àgùntàn àti màlúù jáde nínú tẹ́ńpìlì, ó da ẹyọ owó àwọn tó ń pààrọ̀ owó sílẹ̀, ó sì dojú àwọn tábìlì wọn dé.+ 16 Ó sọ fún àwọn tó ń ta àdàbà pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ yéé sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”*+
-