-
Mátíù 26:6-9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Nígbà tí Jésù wà ní Bẹ́tánì, ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀,+ 7 obìnrin kan tó ní orùba* alabásítà tí wọ́n rọ òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye sí wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í da òróró náà sí orí rẹ̀ nígbà tó ń jẹun.* 8 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, inú bí wọn gan-an, wọ́n sì sọ pé: “Kí ló dé tó ń fi nǹkan ṣòfò báyìí? 9 Ṣe là bá tà á ní owó gọbọi, ká sì fún àwọn aláìní.”
-
-
Jòhánù 12:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí náà, wọ́n se àsè oúnjẹ alẹ́ fún un níbẹ̀, Màtá ń gbé oúnjẹ wá fún wọn,+ Lásárù sì wà lára àwọn tó ń bá a jẹun.* 3 Màríà wá mú ìwọ̀n pọ́n-ùn kan* òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì tó wọ́n gan-an, ó dà á sí ẹsẹ̀ Jésù, ó sì fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ. Òórùn òróró onílọ́fínńdà náà wá gba inú ilé náà kan.+ 4 Àmọ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó máa tó dà á, sọ pé: 5 “Kí ló dé tí a ò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì fún àwọn aláìní?”
-