-
Mátíù 27:11-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Jésù wá dúró níwájú gómìnà, gómìnà sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?” Jésù fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́.”+ 12 Àmọ́ bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà ṣe ń fẹ̀sùn kàn án, kò dáhùn.+ 13 Pílátù wá bi í pé: “Ṣé o ò gbọ́ bí ẹ̀rí tí wọ́n ń jẹ́ lòdì sí ọ ṣe pọ̀ tó ni?” 14 Àmọ́ kò dá a lóhùn, àní kò sọ nǹkan kan, débi pé ó ya gómìnà náà lẹ́nu gan-an.
-