20 Wò ó! obìnrin kan tí ìsun ẹ̀jẹ̀+ ti ń yọ lẹ́nu fún ọdún méjìlá (12) sún mọ́ ọn láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan wajawaja tó wà létí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+21 torí ó ń sọ fún ara rẹ̀ ṣáá, pé: “Tí mo bá ṣáà ti fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ara mi á yá.”
27 Nígbà tó gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, ó gba àárín èrò wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀,+28 torí ó ń sọ ṣáá pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.”+
56 Níbikíbi tó bá sì ti wọ àwọn abúlé, ìlú tàbí ìgbèríko, wọ́n máa gbé àwọn aláìsàn sí àwọn ibi tí wọ́n ti ń tajà, wọ́n á sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kí wọ́n fọwọ́ kan wajawaja etí aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán.+ Ara gbogbo àwọn tó fọwọ́ kàn án sì yá.