-
Mátíù 4:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Èṣù tún mú un lọ sí òkè kan tó ga lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn án.+ 9 Ó sọ fún un pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni màá fún ọ tí o bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” 10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
-