-
Máàkù 2:3-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Wọ́n gbé alárùn rọpárọsẹ̀ kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn mẹ́rin ló gbé e.+ 4 Àmọ́ wọn ò lè gbé e tààràtà dé ọ̀dọ̀ Jésù torí àwọn èrò, nítorí náà, wọ́n ṣí òrùlé ibi tí Jésù wà, wọ́n dá ihò lu síbẹ̀, wọ́n sì gba ojú ihò náà sọ ibùsùn tí alárùn rọpárọsẹ̀ náà dùbúlẹ̀ sí kalẹ̀. 5 Nígbà tí Jésù rí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní,+ ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: “Ọmọ, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 6 Àwọn akọ̀wé òfin kan wà níbẹ̀, wọ́n jókòó, wọ́n ń rò ó lọ́kàn pé:+ 7 “Kí ló dé tí ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ọ̀rọ̀ òdì ló ń sọ. Ta ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 8 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù fòye mọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ pé ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn nìyẹn, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro àwọn nǹkan yìí lọ́kàn yín?+ 9 Èwo ló rọrùn jù, láti sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ àbí láti sọ pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa rìn’? 10 Àmọ́ kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ èèyàn+ ní àṣẹ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini láyé—”+ ó sọ fún alárùn rọpárọsẹ̀ náà pé: 11 “Mò ń sọ fún ọ, Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sílé rẹ.” 12 Ló bá dìde, ó gbé ibùsùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì rìn jáde níwájú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sọ pé: “A ò rí irú èyí rí.”+
-