-
Jòhánù 16:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Jésù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ bi òun ní ìbéèrè, torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé torí mo sọ pé: ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi,’ lẹ ṣe ń bi ara yín lọ́rọ̀ yìí? 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.+
-