-
Mátíù 7:3-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kí ló wá dé tí ò ń wo pòròpórò tó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, àmọ́ tí o ò kíyè sí igi ìrólé tó wà nínú ojú tìrẹ?+ 4 Àbí báwo lo ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí n bá ọ yọ pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ,’ nígbà tó jẹ́ pé, wò ó! igi ìrólé wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ? 5 Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ, ìgbà yẹn lo máa wá ríran kedere láti yọ pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.
-