12 Jálẹ̀ àwọn ìran yín, gbogbo ọmọkùnrin tó wà láàárín yín tó jẹ́ ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́,*+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá bí nínú ilé àti ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ* yín àmọ́ tí ẹ fi owó yín rà lọ́wọ́ àjèjì.
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí obìnrin kan bá lóyún,* tó sì bímọ ọkùnrin, ọjọ́ méje ni kí obìnrin náà fi jẹ́ aláìmọ́, bó ṣe jẹ́ ní àwọn ọjọ́ ìdọ̀tí nígbà tó ń ṣe nǹkan oṣù.+3 Ní ọjọ́ kẹjọ, kí wọ́n dá adọ̀dọ́+ ọmọkùnrin náà.*