-
1 Àwọn Ọba 10:4-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà rí gbogbo ọgbọ́n Sólómọ́nì+ àti ilé tó kọ́,+ 5 oúnjẹ orí tábìlì rẹ̀,+ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń jókòó, bó ṣe ṣètò iṣẹ́ àwọn tó ń gbé oúnjẹ fún un àti aṣọ tí wọ́n ń wọ̀, àwọn agbọ́tí rẹ̀ àti àwọn ẹbọ sísun tó ń rú déédéé ní ilé Jèhófà, ẹnu yà á gan-an.* 6 Nítorí náà, ó sọ fún ọba pé: “Òótọ́ ni ìròyìn tí mo gbọ́ ní ilẹ̀ mi nípa àwọn àṣeyọrí* rẹ àti ọgbọ́n rẹ. 7 Àmọ́ mi ò gba ìròyìn náà gbọ́ títí mo fi wá fojú ara mi rí i. Wò ó! Ohun tí mo gbọ́ kò tiẹ̀ tó ìdajì rárá. Ọgbọ́n rẹ àti aásìkí rẹ kọjá àwọn ohun tí mo gbọ́.
-