20 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run,+ níbi tí òólá kò ti lè jẹ nǹkan run, tí nǹkan ò ti lè dípẹtà,+ tí àwọn olè kò ti lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. 21 Torí ibi tí ìṣúra yín bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn yín náà máa wà.
18 Sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe rere, àní kí wọ́n máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere, kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́,* kí wọ́n ṣe tán láti máa fúnni,+19 kí wọ́n máa to ìṣúra tí kò lè díbàjẹ́ jọ láti fi ṣe ìpìlẹ̀ tó dáa fún ọjọ́ iwájú,+ kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.+