-
Máàkù 2:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Lẹ́yìn náà, nígbà tó ń jẹun* nílé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun,* torí pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń tẹ̀ lé e.+ 16 Àmọ́ nígbà tí àwọn akọ̀wé òfin lára àwọn Farisí rí i pé ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àwọn agbowó orí jẹun, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ṣé ó máa ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun ni?”
-
-
Lúùkù 5:29, 30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Léfì wá gbà á lálejò, ó se àsè rẹpẹtẹ fún un nílé rẹ̀, àwọn agbowó orí àti àwọn míì tó ń bá wọn jẹun* sì pọ̀ gan-an níbẹ̀.+ 30 Ni àwọn Farisí àti àwọn tó jẹ́ akọ̀wé òfin lára wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń bá àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, tí ẹ sì ń bá wọn mu?”+
-