20 Ó sọ fún wọn pé: “Torí ìgbàgbọ́ yín kéré ni. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.”+
21 Jésù fèsì pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, tí ẹ ò sì ṣiyèméjì, ohun tí mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan kọ́ lẹ máa lè ṣe, àmọ́ tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ ó máa ṣẹlẹ̀.+
23 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ tí kò sì ṣiyèméjì nínú ọkàn rẹ̀, àmọ́ tó ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ máa rí bẹ́ẹ̀, ó máa rí bẹ́ẹ̀ fún un.+