-
Jòhánù 18:25-27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Símónì Pétérù wà lórí ìdúró níbẹ̀, ó ń yáná. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sẹ́, ó sì sọ pé: “Rárá o.”+ 26 Ọ̀kan lára àwọn ẹrú àlùfáà àgbà, tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ dà nù+ sọ pé: “Mo rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọgbà, àbí mi ò rí ọ?” 27 Àmọ́ Pétérù tún sẹ́, àkùkọ sì kọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+
-