23 Torí gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀, wọn ò sì kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run,+24 bí a ṣe pè wọ́n ní olódodo dà bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́+ tí wọ́n rí gbà nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ èyí tó wá nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ tí ìràpadà tí Kristi Jésù san mú kó ṣeé ṣe.+
5 Nítorí ó ti yàn wá ṣáájú+ kí ó lè sọ wá dọmọ+ nípasẹ̀ Jésù Kristi, torí ohun tí ó wù ú tí ó sì fẹ́ nìyẹn,+6 kí a lè yìn ín nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ ológo+ tó fi jíǹkí wa nípasẹ̀ àyànfẹ́ rẹ̀.+