39 Ó lọ síwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé:+ “Baba mi, tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife+ yìí ré mi kọjá. Síbẹ̀, kì í ṣe bí mo ṣe fẹ́, àmọ́ bí ìwọ ṣe fẹ́.”+
30 Mi ò lè dá nǹkan kan ṣe lérò ara mi. Ohun tí mò ń gbọ́ ni mo fi ń ṣèdájọ́, òdodo sì ni ìdájọ́ mi,+ torí kì í ṣe ìfẹ́ ara mi ni mò ń wá, ìfẹ́ ẹni tó rán mi ni.+