42 Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn alákòóso pàápàá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lóòótọ́,+ àmọ́ wọn ò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí àwọn Farisí, kí wọ́n má bàa lé wọn kúrò nínú sínágọ́gù;+
7 Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbilẹ̀ nìṣó,+ iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń pọ̀ sí i gidigidi+ ní Jerúsálẹ́mù; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba* ìgbàgbọ́ náà.+