ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 21:8, 9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ṣe ejò kan tó dà bí ejò olóró,* kí o sì gbé e kọ́ sára òpó. Tí ejò bá ṣán ẹnikẹ́ni, onítọ̀hún máa ní láti wò ó kó má bàa kú.” 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fi bàbà ṣe ejò+ kan, ó sì gbé e kọ́ sára òpó+ náà. Nígbàkigbà tí ejò bá ṣán ẹnì kan, tó sì wo ejò bàbà náà, ẹni náà ò ní kú.+

  • Dáníẹ́lì 7:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “Mò ń wò nínú ìran òru, sì wò ó! ẹnì kan bí ọmọ èèyàn+ ń bọ̀ pẹ̀lú ìkùukùu* ojú ọ̀run; a jẹ́ kó wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,+ wọ́n sì mú un wá sún mọ́ iwájú Ẹni yẹn.

  • Mátíù 26:64
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 64 Jésù sọ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ ti sọ ọ́. Àmọ́ mò ń sọ fún yín pé: Láti ìsinsìnyí lọ, ẹ máa rí Ọmọ èèyàn+ tó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára,+ tó sì ń bọ̀ lórí àwọn àwọsánmà* ojú ọ̀run.”+

  • Jòhánù 3:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Àti pé bí Mósè ṣe gbé ejò sókè ní aginjù,+ bẹ́ẹ̀ náà la gbọ́dọ̀ gbé Ọmọ èèyàn sókè,+

  • Jòhánù 12:32, 33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 Síbẹ̀, tí a bá gbé mi sókè kúrò ní ayé,+ màá fa onírúurú èèyàn sọ́dọ̀ ara mi.” 33 Ní tòótọ́, ó ń sọ èyí láti jẹ́ kí wọ́n mọ irú ikú tó máa tó kú.+

  • Gálátíà 3:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Kristi rà wá,+ ó tú wa sílẹ̀+ lábẹ́ ègún Òfin bó ṣe di ẹni ègún dípò wa, nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni ègún ni ẹni tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́