10 Ṣé o ò gbà pé mo wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba àti pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ni?+ Kì í ṣe èrò ara mi+ ni àwọn nǹkan tí mò ń sọ fún yín, àmọ́ Baba tó ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀.
21 kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan,+ bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ,+ kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, kí ayé lè gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.