19 Ó wá sọ fún àwọn èrò náà pé kí wọ́n jókòó* sórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó wo ojú ọ̀run, ó sì súre,+ lẹ́yìn tó bu búrẹ́dì náà, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì fún àwọn èrò náà.
34 Ó gbójú sókè ọ̀run, ó mí kanlẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Éfátà,” tó túmọ̀ sí, “Là.” 35 Ni etí ọkùnrin náà bá là,+ kò níṣòro ọ̀rọ̀ sísọ mọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ dáadáa.