24 “Torí náà, gbogbo ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tó sì ṣe é máa dà bí ọkùnrin kan tó ní òye, tó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.+25 Òjò sì rọ̀, omi kún àkúnya, ìjì sì fẹ́ lu ilé náà, àmọ́ kò wó, torí pé orí àpáta ni ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà.
25 Àmọ́ ẹni tó bá ń fara balẹ̀ wo inú òfin pípé+ tó jẹ́ ti òmìnira, tí kò sì yéé wò ó, kì í ṣe olùgbọ́ tó ń gbàgbé, àmọ́ ó ti di olùṣe iṣẹ́ náà; ohun tó ń ṣe á sì máa múnú rẹ̀ dùn.+