-
Jòhánù 12:4-6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àmọ́ Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, tó máa tó dà á, sọ pé: 5 “Kí ló dé tí a ò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) owó dínárì,* ká sì fún àwọn aláìní?” 6 Kì í ṣe torí pé ọ̀rọ̀ àwọn aláìní jẹ ẹ́ lógún ló ṣe sọ ọ̀rọ̀ yìí o, àmọ́ torí pé olè ni, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, ó sì máa ń jí owó inú rẹ̀.
-