16 Ẹ̀yin kọ́ lẹ yàn mí, èmi ni mo yàn yín, mo sì yàn yín pé kí ẹ lọ, kí ẹ túbọ̀ máa so èso, kí èso yín ṣì máa wà, kó lè jẹ́ pé tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fún yín.+
23 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ ò ní bi mí ní ìbéèrè kankan rárá. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba,+ ó máa fún yín ní orúkọ mi.+