19 Àmọ́ tí wọ́n bá ti fà yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn;+20 torí kì í kàn ṣe ẹ̀yin lẹ̀ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ ẹ̀mí Baba yín ló ń gbẹnu yín sọ̀rọ̀.+
13 Àmọ́ tí ìyẹn* bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ ó máa darí yín sínú gbogbo òtítọ́, torí kì í ṣe èrò ara rẹ̀ ló máa sọ, àmọ́ ohun tó gbọ́ ló máa sọ, ó sì máa kéde àwọn nǹkan tó ń bọ̀ fún yín.+
27 Ní tiyín, yíyàn tó yàn yín+ kò kúrò nínú yín, ẹ ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni máa kọ́ yín; àmọ́, yíyàn tó yàn yín ń kọ́ yín ní ohun gbogbo,+ òótọ́ ni, kì í ṣe irọ́. Kí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe kọ́ yín gẹ́lẹ́.+