17 Jésù sọ fún un pé: “Má rọ̀ mọ́ mi mọ́, torí mi ò tíì gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba. Àmọ́ lọ bá àwọn arákùnrin mi,+ kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi+ àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi+ àti Ọlọ́run yín.’”
28 Àmọ́ nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, ìgbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ á fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀,+ kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.+