-
Mátíù 9:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àwọn akọ̀wé òfin kan wá ń sọ fún ara wọn pé: “Ọ̀gbẹ́ni yìí ń sọ̀rọ̀ òdì.” 4 Jésù mọ ohun tí wọ́n ń rò, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro ohun burúkú nínú ọkàn yín?+
-
-
Máàkù 2:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Àwọn akọ̀wé òfin kan wà níbẹ̀, wọ́n jókòó, wọ́n ń rò ó lọ́kàn pé:+ 7 “Kí ló dé tí ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀ báyìí? Ọ̀rọ̀ òdì ló ń sọ. Ta ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini yàtọ̀ sí Ọlọ́run nìkan?”+ 8 Àmọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù fòye mọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ pé ohun tí wọ́n ń rò lọ́kàn nìyẹn, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń ro àwọn nǹkan yìí lọ́kàn yín?+
-