12 Ṣùgbọ́n ó fún gbogbo àwọn tó gbà á ní àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run,+ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.+13 A ò bí wọn látinú ẹ̀jẹ̀ tàbí látinú ìfẹ́ ti ara tàbí látinú ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ a bí wọn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+
3 Ẹ yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, torí nínú àánú rẹ̀ tó pọ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun+ ká lè ní ìrètí tó wà láàyè+ nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú ikú,+
23 Torí a ti fún yín ní ìbí tuntun,+ kì í ṣe nípasẹ̀ irúgbìn* tó lè bà jẹ́, àmọ́ nípasẹ̀ irúgbìn tí kò lè bà jẹ́,+ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run alààyè, tó wà títí láé.+