4 Nígbà tó sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Símónì pé: “Wa ọkọ̀ lọ síbi tí omi ti jìn, kí ẹ sì rọ àwọ̀n yín sísàlẹ̀ láti kó ẹja.” 5 Àmọ́ Símónì fèsì pé: “Olùkọ́, gbogbo òru la fi ṣiṣẹ́ kára, a ò sì rí nǹkan kan mú,+ ṣùgbọ́n torí ohun tí o sọ, màá rọ àwọ̀n náà sísàlẹ̀.”