-
Ìṣe 11:5-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 “Ìlú Jópà ni mo wà tí mo ti ń gbàdúrà, mo sì rí ìran kan nígbà tí mo wà lójú ìran, ohun* kan ń sọ̀ kalẹ̀ bọ̀ bí aṣọ ọ̀gbọ̀ fífẹ̀ tí a fi igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì wá tààrà sọ́dọ̀ mi.+ 6 Bí mo ṣe tẹjú mọ́ ọn, mo rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin orí ilẹ̀, àwọn ẹran inú igbó, àwọn ẹran tó ń fàyà fà* àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. 7 Mo tún gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi pé: ‘Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!’ 8 Àmọ́ mo sọ pé: ‘Rárá o, Olúwa, torí ohun tó jẹ́ ẹlẹ́gbin tàbí aláìmọ́ kò wọ ẹnu mi rí.’ 9 Nígbà kejì, ohùn tó wá láti ọ̀run náà sọ pé: ‘Yéé pe àwọn ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.’ 10 Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà kẹta, a sì fa gbogbo rẹ̀ pa dà sókè ọ̀run.
-