17 Torí Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ Ọlọ́run àwọn ọlọ́run+ àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run tó tóbi, tó lágbára, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tí kì í ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni,+ tí kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
7 Ẹ jẹ́ kí ìbẹ̀rù Jèhófà wà lọ́kàn yín.+ Ẹ máa kíyè sára nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí pé kò sí àìṣẹ̀tọ́,+ kò sí ojúsàájú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò sí gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.”+