9 Ọlọ́run tún sọ fún Ábúráhámù pé: “Ní tìrẹ, kí o pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ jálẹ̀ àwọn ìran wọn. 10 Májẹ̀mú tí mo bá ọ dá nìyí, òun sì ni ìwọ àti àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò máa pa mọ́: Gbogbo ọkùnrin tó wà láàárín yín gbọ́dọ̀ dádọ̀dọ́.*+
48 Tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín, tó sì fẹ́ ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá láti bọlá fún Jèhófà, kí gbogbo ọkùnrin ilé rẹ̀ dádọ̀dọ́.* Ìgbà yẹn ló lè ṣe ayẹyẹ náà, yóò sì dà bí ọmọ ìbílẹ̀. Àmọ́ aláìdádọ̀dọ́* ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀.+
2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí obìnrin kan bá lóyún,* tó sì bímọ ọkùnrin, ọjọ́ méje ni kí obìnrin náà fi jẹ́ aláìmọ́, bó ṣe jẹ́ ní àwọn ọjọ́ ìdọ̀tí nígbà tó ń ṣe nǹkan oṣù.+3 Ní ọjọ́ kẹjọ, kí wọ́n dá adọ̀dọ́+ ọmọkùnrin náà.*