5 Nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn alákòóso wọn gbìyànjú láti dójú tì wọ́n, kí wọ́n sì sọ wọ́n lókùúta,+ 6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sá lọ sí àwọn ìlú Likaóníà, Lísírà àti Déébè àti àwọn abúlé tó wà ní àyíká.+ 7 Wọ́n ń kéde ìhìn rere níbẹ̀.